Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| AWỌN ọkunrin Israeli si ti bura ni Mispe, pe, Ẹnikan ninu wa ki yio fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Benjamini li aya. |
| 2 |
| Awọn enia na si wá si Beti-eli, nwọn si joko nibẹ̀ titi di aṣalẹ niwaju Ọlọrun, nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun gidigidi. |
| 3 |
| Nwọn si wipe, OLUWA, Ọlọrun Israeli, ẽṣe ti o fi ri bayi ni Israeli, ti ẹ̀ya kan fi bùku li oni ninu awọn enia Israeli? |
| 4 |
| O si ṣe ni ijọ́ keji, awọn enia na dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si mọ pẹpẹ kan nibẹ̀, nwọn si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia. |
| 5 |
| Awọn ọmọ Israeli si wipe, Tali o wà ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli ti kò bá ijọ gòke tọ̀ OLUWA wá? Nitoripe nwọn ti bura nla niti ẹniti kò ba tọ̀ OLUWA wá ni Mispe, wipe, Pipa li a o pa a. |
| 6 |
| Awọn ọmọ Israeli si kãnu nitori Benjamini arakunrin wọn, nwọn si wipe, A ke ẹ̀ya kan kuro ni Israeli li oni. |
| 7 |
| Awa o ha ti ṣe niti obinrin fun awọn ti o kù, awa sá ti fi OLUWA bura pe, awa ki yio fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn li aya. |
| 8 |
| Nwọn si wipe, Ewo ni ninu awọn ẹ̀ya Israeli ti kò tọ̀ OLUWA wá ni Mispe? Si kiyesi i, kò sí ẹnikan ni ibudó ti o ti Jabeṣi-gileadi wá si ijọ. |
| 9 |
| Nitori nigbati a kà awọn enia na, si kiyesi i, kò sí ẹnikan nibẹ̀ ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi. |
| 10 |
| Ijọ si rán ẹgbã mẹfa ọkunrin ninu awọn akọni sibẹ̀, nwọn si fi aṣẹ fun wọn pe, Ẹ lọ ẹ si fi oju idà kọlù awọn ara Jabeṣi-gileadi, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọ wẹrẹ. |
| 11 |
| Eyiyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: gbogbo ọkunrin, ati gbogbo obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin li ẹnyin o parun patapata. |
| 12 |
| Nwọn si ri irinwo wundia ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi, ti kò ti imọ̀ ọkunrin nipa ibadapọ̀: nwọn si mú wọn wá si ibudó ni Ṣilo, ti o wà ni ilẹ Kenaani. |
| 13 |
| Gbogbo ijọ si ranṣẹ lọ bá awọn ọmọ Benjamini ti o wà ninu okuta Rimmoni sọ̀rọ, nwọn si fi alafia lọ̀ wọn. |
| 14 |
| Benjamini si pada li akokò na; nwọn si fun wọn li obinrin ti nwọn dasi ninu awọn obinrin Jabeṣi-gileadi: ṣugbọn sibẹ̀ nwọn kò si kari wọn. |
| 15 |
| Awọn enia na si kãnu nitori Benjamini, nitoripe OLUWA ṣe àlàfo ninu awọn ẹ̀ya Israeli. |
| 16 |
| Nigbana li awọn àgba ijọ wipe, Kini awa o ṣe niti obinrin fun awọn iyokù, nitoripe a ti pa gbogbo awọn obinrin run kuro ni Benjamini? |
| 17 |
| Nwọn si wipe, Ilẹ-iní kan yio wà fun awọn ti o ti sálà ni Benjamini, ki ẹ̀ya kan ki o má ba parun kuro ni Israeli. |
| 18 |
| Ṣugbọn awa kò lè fi aya fun wọn ninu awọn ọmọbinrin wa: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti bura, wipe, Egún ni fun ẹniti o ba fi aya fun Benjamini. |
| 19 |
| Nwọn si wipe, Kiyesi i, ajọ OLUWA wà li ọdọdún ni Ṣilo ni ìha ariwa Beti-eli, ni ìha ìla-õrùn ti opópo ti o lọ soke lati Beti-eli lọ titi dé Ṣekemu, ati ni ìha gusù ti Lebona. |
| 20 |
| Nwọn si fi aṣẹ fun awọn ọmọ Benjamini wipe, Ẹ lọ ki ẹ si ba sinu ọgbà-àjara; |
| 21 |
| Ki ẹ si wò, si kiyesi i, bi awọn ọmọbinrin Ṣilo ba jade wá lati jó ninu ijó wọnni, nigbana ni ki ẹnyin ki o jade lati inu ọgbà-àjara wá, ki olukuluku ọkunrin nyin ki o si mú aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Ṣilo, ki ẹnyin ki o si lọ si ilẹ Benjamini. |
| 22 |
| Yio si ṣe, nigbati awọn baba wọn tabi awọn arakunrin wọn ba tọ̀ wa wá lati wijọ, awa o si wi fun wọn pe, Ẹ ṣãnu wọn nitori wa: nitoriti awa kò mú aya olukuluku fun u li ogun na: bẹ̃ni ki iṣe ẹnyin li o fi wọn fun wọn; nigbana ni ẹnyin iba jẹbi. |
| 23 |
| Awọn ọmọ Benjamini si ṣe bẹ̃, nwọn si mú aya, gẹgẹ bi iye wọn, ninu awọn ẹniti njó, awọn ti nwọn múlọ; nwọn si lọ nwọn pada si ilẹ-iní wọn nwọn si kọ ilu wọnni, nwọn si joko sinu wọn. |
| 24 |
| Nigbana li awọn ọmọ Israeli si lọ lati ibẹ̀, olukuluku enia si ẹ̀ya tirẹ̀, ati si idile tirẹ̀, nwọn si jade lati ibẹ̀ lọ olukuluku enia si ilẹ-iní tirẹ̀. |
| 25 |
| Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/judges/021.mp3
21
21