Si wõ, nisisiyi, ọba na nrìn niwaju nyin: emi si ti di arugbo, mo si hewu; si wõ, awọn ọmọ mi si mbẹ lọdọ nyin: emi ti nrìn niwaju nyìn lati igba ewe mi wá titi o fi di oni yi.
Wõ, emi nĩ, jẹri si mi niwaju Oluwa, ati niwaju ẹni ami-ororo rẹ̀: malu tani mo gbà ri? tabi kẹtẹkẹtẹ tani mo gbà ri? tani mo rẹjẹ ri? tani mo jẹ ni ìya ri? tabi lọwọ́ tali emi gbà owo abẹtẹlẹ kan ri lati fi bo ara mi loju? emi o si sãn pada fun nyin.
Nigbati Jakobu wá si Egipti, ti awọn baba kigbe pe Oluwa, Oluwa si rán Mose ati Aaroni, awọn ẹniti o mu awọn baba nyin ti ilẹ Egypti jade wá, o si mu wọn joko nihinyi.
Nwọn si kigbe pe Oluwa, nwọn si wipe, Awa ti dẹsẹ̀, nitoripe awa ti kọ̀ Oluwa silẹ, awa si ti nsin Baalimu ati Aṣtaroti: ṣugbọn nisisiyi, gba wa lọwọ́ awọn ọta wa, awa o si sìn ọ.
Nigbati ẹnyin si ri pe Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni tọ̀ nyin wá, ẹnyin wi fun mi pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ọba yio jẹ lori wa: nigbati Oluwa Ọlọrun nyin jẹ ọba nyin.
Bi ẹnyin ba bẹ̀ru Oluwa, ti ẹnyin si sin i, ti ẹnyin si gbọ́ ohùn rẹ̀, ti ẹnyin ko si tapa si ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ati ọba nyin ti o jẹ lori nyin yio ma wà lẹhin Oluwa Ọlọrun nyin.
Oni ki ọjọ ikore ọka bi? emi o kepe Oluwa, yio si ran ãra ati ojò; ẹnyin o si mọ̀, ẹnyin o si ri pe iwabuburu nyin pọ̀, ti ẹnyin ṣe li oju Oluwa ni bibere ọba fun ara nyin.
Gbogbo enia si wi fun Samueli pe, Gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ fun awọn iranṣẹ rẹ, ki awa ki o má ba kú: nitori ti awa ti fi buburu yi kun gbogbo ẹṣẹ wa ni bibere ọba fun ara wa.