Ṣugbọn Jonatani ọmọ Saulu fẹràn Dafidi pupọ: Jonatani si sọ fun Dafidi pe, Saulu baba mi nwá ọ̀na ati pa ọ, njẹ, mo bẹ̀ ọ, kiyesi ara rẹ titi di owurọ, ki o si joko nibi ikọ̀kọ, ki o si sa pamọ.
Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ.
Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ?
Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na.
Saulu si rán onṣẹ si ile Dafidi, lati ma ṣọ ọ ati lati pa a li owurọ: Mikali aya Dafidi si wi fun u pe, Bi iwọ kò ba gbà ẹmi rẹ là li alẹ yi, li ọla li a o pa ọ.
Saulu si wi fun Mikali pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi tàn mi jẹ bẹ̃, ti iwọ si fi jọwọ ọta mi lọwọ lọ, ti on si bọ? Mikali si da Saulu lohùn pe, On wi fun mi pe, Jẹ ki emi lọ; ẽṣe ti emi o fi pa ọ?
Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi: nigbati nwọn ri ẹgbẹ awọn wolĩ ti nsọtẹlẹ, ati Samueli ti o duro bi olori wọn, Ẹmi Ọlọrun si bà le awọn onṣẹ Saulu, awọn na si nsọtẹlẹ.
On na si lọ si Rama, o si de ibi kanga nla kan ti o wà ni Seku: o si bere, o si wipe, Nibo ni Samueli ati Dafidi gbe wà? ẹnikan si wipe, Wõ, nwọn mbẹ ni Naoti ni Rama.
On si bọ aṣọ rẹ̀ silẹ, o si sọtẹlẹ pẹlu niwaju Samueli, o si dubulẹ nihoho ni gbogbo ọjọ na, ati ni gbogbo oru na. Nitorina nwọn si wipe, Saulu pẹlu ha wà ninu awọn woli?