× Language Yuroopu Russian Belarusian Ukrainian Polish Serbian Bulgarian Slovakian Czech Romanian Moldovian Azerbaijan Armenian Georgia Albanian Avar Bashkir Tatar Chechen Slovenian Croatian Estonian Latvian Lithuanian Hungarian Finnish Norwegian Swedish Icelandic Greek Makedonia German Bavarian Dutch Danish Welsh Gaelic .Dè Irish French Basque Catalan Italian Galacian Romani Bosnian Ariwa Amerika English Ila gusu Amerika Spanish Portuguese Guarani Quechuan Aymara Central America Jamaican Nahuatl Kiche Qeqchi Haitian Ila-oorun Asia Chinese Japanese Korean Mongolia Uyguru Hmong Guusu ila oorun Esia Malaysian Burmese Hakha Chin Nepali Cebuano Tagalog Cambodian Thai Indonesian Vietnamese Javanese Lao Iban IuMien Kachin Lahu Aceh Balinese Bugis Pampanga Sasak Shan Waray Guusu Asia Hindi Оdia Awadhi Mizo Kannada Malayalam Marathi Gujarati Tamil Telugu Punjabi Kurukh Ara Assamese Maithili Bengali Urdu Sinhala Dogri Haryanvi Meitei Konkani Santali Sindhi Koya Thado Sanskrit Devanagari Adilabad Gondi Ahirani Balochi Bundeli Chhattisgarhi Garhwali Kangri Kumaoni Mewari Munda Sadri Seraiki Shekhawati Sylheti Aringbungbun Esia Kyrgyz Usibek Tajik Turkmen Kazakhstan Karakalpak Arin Ila-Oorun Turkish Hebrew Arabic Persian Kurdish Pasto Coptic Afirika Afrikaans Xhosa Zulu Ndebele Sotho Amharic Wolaytta Nigerian Mossi Ika Dinka Kabyle Ewe Swahili Morocco Somalian Shona Madagascar Igbo Lingala Baoule Siswati Tsonga Tswana Gambian Yoruba Kamba Kinyarwanda Hausa Chewa Luo Makua Dyula Fulfulde Kalenjin Kikuyu Kikwango Kirundi Krio Nigerian Pidgin Oromo Tshiluba Tshivenda Twi Umbundu Lugbara Luguru Pular Gussi Maasai Turkana Moba Nuer Shilluk Tamasheq Makonde Bemba Fon Hadiyya Ibibio Kimbundu Kimiiru Lango Liberian Kreyol Lomwe Mende Morisyen Ndau Nyankole Sena Sidamo Soga Songe Sukuma Tarifit Teso Tiv Zande Orile-ede Australia New Zealand Papua New Guinea Awọn Ede Atijọ Aramaic Latin Esperanto 1 1 1 YCE 20142010YCE1 1 1 1 Ọba GẹnẹsisiEksoduLefitikuNumeriDeuteronomiJoṣuaOnidajọRutu1 Samuẹli2 Samuẹli1 Ọba2 Ọba1 Kronika2 KronikaEsraNehemiahEsteriJobuSaamuÒweOniwaasuOrin SolomoniIsaiahJeremiahẸkun JeremiahEsekiẹliDaniẹliHoseaJoẹliAmosiỌbadiahJonaMikaNahumuHabakukuSefaniahHagaiSekariahMalaki--- --- ---MatiuMarkuLukuJohanuÌṣe àwọn AposteliRomu1 Kọrinti2 KọrintiGalatiaEfesuFilipiKolose1 Tẹsalonika2 Tẹsalonika1 Timotiu2 TimotiuTituFilemoniHeberuJakọbu1 Peteru2 Peteru1 Johanu2 Johanu3 JohanuJudaÌfihàn1 1 1 1 123456789101112131415161718192021221 1 1 : 1 12345678910111213141516171819202122232425262728293031323334353637383940414243444546474849505152531 1 1 Yoruba Bible 1 Ọba 1 Fipamọ Awọn akọsilẹ 1DAFIDI ọba si di arugbo, ọjọ rẹ̀ si pọ̀; nwọn si fi aṣọ bò o lara, ṣugbọn kò mõru.2Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Jẹ ki a wá ọmọbinrin kan, wundia, fun Oluwa mi, ọba: ki o si duro niwaju ọba, ki o si ṣikẹ́ rẹ̀, ki o si dubulẹ li õkan-aiya rẹ̀, oluwa mi, ọba yio si mõru.3Nwọn si wá ọmọbinrin arẹwà kan ka gbogbo agbegbe Israeli, nwọn si ri Abiṣagi, ara Ṣunemu, nwọn si mu u tọ̀ ọba wá.4Ọmọbinrin na si ṣe arẹwà gidigidi, o si nṣikẹ́ ọba, o si nṣe iranṣẹ fun u; ṣugbọn ọba kò si mọ̀ ọ.5Adonijah, ọmọ Haggiti, si gbe ara rẹ̀ ga, wipe, emi ni yio jọba: o si mura kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin, ati ãdọta ọkunrin lati sare niwaju rẹ̀.6Baba rẹ̀ kò si bà a ninu jẹ rí, pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe bayi? On si ṣe enia ti o dara gidigidi: iya rẹ̀ si bi i le Absalomu.7O si ba Joabu, ọmọ Seruiah, ati Abiatari, alufa gbèro: nwọn si nràn Adonijah lọwọ.8Ṣugbọn Sadoku alufa, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati Natani woli, ati Ṣimei, ati Rei, ati awọn ọkunrin alagbara ti mbẹ lọdọ Dafidi, kò wà pẹlu Adonijah.9Adonijah si pa agutan ati malu ati ẹran ọ̀sin ti o sanra nibi okuta Soheleti, ti mbẹ lẹba Enrogeli, o si pè gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ ọba, ati gbogbo ọkunrin Juda, iranṣẹ ọba:10Ṣugbọn Natani, alufa, ati Benaiah ati awọn ọkunrin alagbara, ati Solomoni arakunrin rẹ̀ ni kò pè.11Natani si wi fun Batṣeba, iya Solomoni pe, Iwọ kò gbọ́ pe, Adonijah, omọ Haggiti jọba, Dafidi, oluwa wa, kò si mọ̀?12Nitorina, wá nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, emi o si fun ọ ni ìmọ, ki iwọ ki o le gbà ẹmi rẹ là, ati ẹmi Solomoni ọmọ rẹ.13Lọ, ki o si tọ̀ Dafidi, ọba lọ, ki o si wi fun u pe, Ọba, oluwa mi, ṣe iwọ li o bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, ni yio jọba lẹhin mi, on ni o si joko lori itẹ mi? ẽṣe ti Adonijah fi jọba?14Kiyesi i, bi iwọ ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, emi o si tẹle ọ, emi o si wá ikún ọ̀rọ rẹ.15Batṣeba si tọ̀ ọba lọ ni iyẹ̀wu: ọba si gbó gidigidi: Abiṣagi, ara Ṣunemu, si nṣe iranṣẹ fun ọba.16Batṣeba si tẹriba, o si wolẹ fun ọba. Ọba si wipe, Kini iwọ nfẹ?17On si wi fun u pe, oluwa mi, iwọ fi Oluwa Ọlọrun rẹ bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi.18Sa wò o, nisisiyi, Adonijah jọba; iwọ, oluwa mi ọba, kò si mọ̀.19O si pa malu ati ẹran ti o li ọra, ati agùtan li ọ̀pọlọpọ, o si pe gbogbo awọn ọmọ ọba, ati Abiatari alufa, ati Joabu balogun: ṣugbọn Solomoni iranṣẹ rẹ ni kò pè.20Ati iwọ, oluwa mi, ọba, oju gbogbo Israeli mbẹ lara rẹ, ki iwọ ki o sọ fun wọn, tani yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀?21Yio si ṣe, nigbati oluwa mi ọba ba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a o si kà emi ati Solomoni ọmọ mi si ẹlẹṣẹ̀.22Si wò o, bi o si ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, Natani woli si wọle.23Nwọn si sọ fun ọba pe, Wò o, Natani woli. Nigbati o si wá siwaju ọba, o wolẹ̀, o si dojubolẹ.24Natani si wipe, oluwa mi, ọba! iwọ ha wipe, Adonijah ni yio jọba lẹhin mi ati pe, on o si joko lori itẹ mi bi?25Nitori o sọkalẹ lọ loni, o si pa malu ati ẹran ọlọra, ati agùtan li ọ̀pọ-lọpọ, o si pè gbogbo awọn ọmọ ọba, ati awọn balogun, ati Abiatari alufa; si wò o, nwọn njẹ, nwọn si nmu niwaju rẹ̀, nwọn si nwipe, Ki Adonijah ọba ki o pẹ.26Ṣugbọn emi, emi iranṣẹ rẹ, ati Sadoku alufa, ati Benaiah ọmọ Jehoiada, ati Solomoni, iranṣẹ rẹ, ni kò pè.27Nkan yi ti ọdọ oluwa mi ọba wá bi? iwọ kò si fi ẹniti yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀ hàn iranṣẹ rẹ?28Dafidi, ọba si dahùn o si wipe, Ẹ pè Batṣeba fun mi. On si wá siwaju ọba, o si duro niwaju ọba,29Ọba si bura, o si wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹniti o ti rà ọkàn mi pada kuro ninu gbogbo ìṣẹ́.30Gẹgẹ bi mo ti fi Oluwa, Ọlọrun Israeli bura fun ọ, wipe, Nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi ni ipò mi, bẹ̃ni emi o ṣe loni yi dandan.31Batṣeba si foribalẹ, o si bọ̀wọ fun ọba, o si wipe, Ki oluwa mi, Dafidi ọba ki o pẹ titi lai.32Dafidi ọba wipe, Ẹ pè Sadoku alufa fun mi, ati Natani woli, ati Benaiah ọmọ Jehoiada. Nwọn si wá siwaju ọba.33Ọba si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn iranṣẹ oluwa nyin, ki ẹ si mu ki Solomoni ọmọ mi ki o gùn ibãka mi, ki ẹ si mu sọkalẹ wá si Gihoni.34Ki ẹ si jẹ ki Sadoku, alufa, ati Natani woli, fi ororo yàn a nibẹ̀ li ọba lori Israeli: ki ẹ si fun fère, ki ẹ si wipe; Ki Solomoni ọba ki o pẹ!35Ki ẹ si goke tọ̀ ọ lẹhin, ki o si wá, ki o si joko lori itẹ mi; on o si jọba ni ipò mi: emi si pa a laṣẹ lati jẹ olori Israeli ati Juda.36Benaiah ọmọ Jehoiada, si da ọba lohùn, o si wipe, Amin: Oluwa, Ọlọrun ọba oluwa mi, wi bẹ̃ pẹlu.37Bi Oluwa ti wà pẹlu oluwa mi ọba, gẹgẹ bẹ̃ni ki o wà pẹlu Solomoni, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ oluwa mi, Dafidi ọba lọ.38Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti si sọkalẹ, nwọn si mu ki Solomoni ki o gùn ibãka Dafidi ọba, nwọn si mu u wá si Gihoni,39Sadoku alufa si mu iwo ororo lati inu agọ, o si dà a si Solomoni lori; nwọn si fun fère; gbogbo enia si wipe, Ki Solomoni ọba ki o pẹ.40Gbogbo enia si goke tọ̀ ọ lẹhin, awọn enia si fun ipè, nwọn si yọ̀ ayọ̀ nlanla, tobẹ̃ ti ilẹ mì fun iró wọn.41Ati Adonijah ati gbogbo awọn ti o pè sọdọ rẹ̀ si gbọ́, nigbati nwọn jẹun tan, Joabu si gbọ́ iró ipè o si wipe: eredi ariwo ilu ti nrọkẹkẹ yi?42Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufa de; Adonijah si wi fun u pe, Mã wolẹ̀; nitoripe alagbara ọkunrin ni iwọ, ati ẹniti nmu ihin-rere wá.43Jonatani si dahùn o si wi fun Adonijah pe, Lõtọ ni, oluwa wa, Dafidi ọba, fi Solomoni jọba.44Ọba si ti rán Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti pẹlu rẹ̀, nwọn si ti mu u ki o gùn ibãka ọba.45Sadoku, alufa ati Natani, woli si ti fi ororo yàn a li ọba ni Gihoni: nwọn si fi ayọ̀ goke lati ibẹ wá, tobẹ̃ ti ilu si nho. Eyi ni ariwo ti ẹ ti gbọ́.46Solomoni si joko lori itẹ ijọba pẹlu.47Awọn iranṣẹ ọba si wá lati sure fun oluwa wa, Dafidi ọba, pe, Ki Ọlọrun ki o mu orukọ Solomoni ki o sàn jù orukọ rẹ lọ, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ rẹ lọ. Ọba si gbadura lori akete.48Ọba si wi bayi pẹlu, Olubukun li Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fun mi li ẹnikan ti o joko lori itẹ mi loni, oju mi si ri i.49Gbogbo awọn ti a pè, ti nwọn wà li ọdọ Adonijah si bẹ̀ru, nwọn si dide, nwọn si lọ olukuluku si ọ̀na rẹ̀.50Adonijah si bẹ̀ru Solomoni, o si dide, o si lọ, o si di iwo pẹpẹ mu.51Nwọn si wi fun Solomoni pe, Wò o, Adonijah bẹ̀ru Solomoni ọba: si kiyesi i, o di iwo pẹpẹ mu, o nwipe, Ki Solomoni ọba ki o bura fun mi loni pe, On kì yio fi idà pa iranṣẹ rẹ̀.52Solomoni si wipe, Bi o ba jẹ fi ara rẹ̀ si ọ̀wọ, irun ori rẹ̀ kan kì yio bọ́ silẹ: ṣugbọn bi a ba ri buburu lọwọ rẹ̀, on o kú.53Solomoni ọba si ranṣẹ, nwọn mu u sọkalẹ lori pẹpẹ. On si wá, o si foribalẹ̀ fun Solomoni ọba: Solomoni si wi fun u pe, Mã lọ ile rẹ.Yoruba Bible No Data Yoruba Bible 1 Ọba 1 00:00:00 00:00:00 0.5x 2.0x https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/1kings/001.mp3 22 1