× Language Yuroopu Russian Belarusian Ukrainian Polish Serbian Bulgarian Slovakian Czech Romanian Moldovian Azerbaijan Armenian Georgia Albanian Avar Bashkir Tatar Chechen Slovenian Croatian Estonian Latvian Lithuanian Hungarian Finnish Norwegian Swedish Icelandic Greek Makedonia German Bavarian Dutch Danish Welsh Gaelic .Dè Irish French Basque Catalan Italian Galacian Romani Bosnian Ariwa Amerika English Ila gusu Amerika Spanish Portuguese Guarani Quechuan Aymara Central America Jamaican Nahuatl Kiche Qeqchi Haitian Ila-oorun Asia Chinese Japanese Korean Mongolia Uyguru Hmong Guusu ila oorun Esia Malaysian Burmese Hakha Chin Nepali Cebuano Tagalog Cambodian Thai Indonesian Vietnamese Javanese Lao Iban IuMien Kachin Lahu Aceh Balinese Bugis Pampanga Sasak Shan Waray Guusu Asia Hindi Оdia Awadhi Mizo Kannada Malayalam Marathi Gujarati Tamil Telugu Punjabi Kurukh Ara Assamese Maithili Bengali Urdu Sinhala Dogri Haryanvi Meitei Konkani Santali Sindhi Koya Thado Sanskrit Devanagari Adilabad Gondi Ahirani Balochi Bundeli Chhattisgarhi Garhwali Kangri Kumaoni Mewari Munda Sadri Seraiki Shekhawati Sylheti Aringbungbun Esia Kyrgyz Usibek Tajik Turkmen Kazakhstan Karakalpak Arin Ila-Oorun Turkish Hebrew Arabic Persian Kurdish Pasto Coptic Afirika Afrikaans Xhosa Zulu Ndebele Sotho Amharic Wolaytta Nigerian Mossi Ika Dinka Kabyle Ewe Swahili Morocco Somalian Shona Madagascar Igbo Lingala Baoule Siswati Tsonga Tswana Gambian Yoruba Kamba Kinyarwanda Hausa Chewa Luo Makua Dyula Fulfulde Kalenjin Kikuyu Kikwango Kirundi Krio Nigerian Pidgin Oromo Tshiluba Tshivenda Twi Umbundu Lugbara Luguru Pular Gussi Maasai Turkana Moba Nuer Shilluk Tamasheq Makonde Bemba Fon Hadiyya Ibibio Kimbundu Kimiiru Lango Liberian Kreyol Lomwe Mende Morisyen Ndau Nyankole Sena Sidamo Soga Songe Sukuma Tarifit Teso Tiv Zande Orile-ede Australia New Zealand Papua New Guinea Awọn Ede Atijọ Aramaic Latin Esperanto 1 1 1 YCE 20142010YCE1 1 1 Hosea GẹnẹsisiEksoduLefitikuNumeriDeuteronomiJoṣuaOnidajọRutu1 Samuẹli2 Samuẹli1 Ọba2 Ọba1 Kronika2 KronikaEsraNehemiahEsteriJobuSaamuÒweOniwaasuOrin SolomoniIsaiahJeremiahẸkun JeremiahEsekiẹliDaniẹliHoseaJoẹliAmosiỌbadiahJonaMikaNahumuHabakukuSefaniahHagaiSekariahMalaki--- --- ---MatiuMarkuLukuJohanuÌṣe àwọn AposteliRomu1 Kọrinti2 KọrintiGalatiaEfesuFilipiKolose1 Tẹsalonika2 Tẹsalonika1 Timotiu2 TimotiuTituFilemoniHeberuJakọbu1 Peteru2 Peteru1 Johanu2 Johanu3 JohanuJudaÌfihàn1 1 1 2 12345678910111213141 1 1 : 1 12345678910111213141516171819202122231 1 1 Yoruba Bible Hosea 2 Fipamọ Awọn akọsilẹ 1Ẹ wi fun awọn arakunrin nyin, Ammi; ati fun awọn arabinrin nyin, Ruhama.2Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀.3Ki emi má ba tú u si ihòho, emi o si gbe e kalẹ bi ọjọ ti a bi i, emi o si ṣe e bi ijù, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a kú.4Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nitoriti nwọn jẹ́ ọmọ agbère.5Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi.6Nitorina kiyesi i, emi o fi ẹgún sagbàra yi ọ̀na rẹ̀ ka, emi o si mọ odi, ti on kì yio fi ri ọ̀na rẹ̀ mọ.7On o si lepa awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kì yio le ba wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana ni yio wipe, Emi o padà tọ̀ ọkọ mi iṣãju lọ; nitoriti o sàn fun mi nigbana jù ti isisiyi lọ.8Nitori on kò ti mọ̀ pe emi li ẹniti o fun u li ọkà, ati ọti-waini titun, ati ororo; ti mo si mu fàdakà ati wurà rẹ̀ pọ̀ si i, ti nwọn fi ṣe Baali.9Nitorina li emi o ṣe padà, emi o si mu ọkà mi kuro li akokò rẹ̀, ati ọti-waini mi ni igbà rẹ̀, emi o si gbà irun agùtan ati ọgbọ̀ mi padà, ti mo ti fi fun u lati bò ihòho rẹ̀.10Nisisiyi li emi o ṣi itiju rẹ̀ silẹ li oju awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ẹnikẹni kì yio si gbà a lọwọ mi.11Emi o si mu ki gbogbo ayọ̀ rẹ̀ de opin, ọjọ asè rẹ̀, oṣù titun rẹ̀, ati ọjọ isimi rẹ̀, gbogbo ọjọ ọ̀wọ rẹ̀.12Emi o si pa ajàra rẹ̀ ati igi ọpọ̀tọ rẹ̀ run, niti awọn ti o ti wipe, Awọn wọnyi li èrè mi ti awọn ayànfẹ́ mi ti fi fun mi; emi o si sọ wọn di igbo, awọn ẹranko igbẹ yio si jẹ wọn.13Emi o si bẹ̀ ọjọ Baalimu wò li ara rẹ̀, ninu eyiti on fi turari joná fun wọn, ti on si fi oruka eti, ati ohun ọ̀ṣọ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọṣọ, ti on si tọ̀ awọn ayànfẹ́ lẹhìn lọ, ti on si gbagbe mi, ni Oluwa wi.14Nitorina, kiyesi i, emi o tàn a, emi o si mu u wá si aginjù, emi o si sọ̀rọ itùnu fun u.15Emi o si fun u ni ọgbà àjara rẹ̀ lati ibẹ̀ wá, ati afonifojì Akori fun ilẹ̀kun ireti: on o si kọrin nibẹ̀, bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ ti o jade lati ilẹ Egipti wá.16Yio si ṣe li ọjọ na, iwọ o pè mi ni Iṣi; iwọ kì yio si pè mi ni Baali mọ, ni Oluwa wi,17Nitori emi o mu orukọ awọn Baali kuro li ẹnu rẹ̀, a kì yio si fi orukọ wọn ranti wọn mọ́.18Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ́ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu.19Emi o si fẹ́ ọ fun ara mi titi lai; nitõtọ, emi o si fẹ́ ọ fun ara mi ni ododo, ni idajọ, ati ni iyọ́nu, ati ni ãnu.20Emi o tilẹ fẹ́ ọ fun ara mi ni otitọ, iwọ o si mọ̀ Oluwa.21Yio si ṣe li ọjọ na, emi o dahùn, emi o dá awọn ọrun li ohùn, nwọn o si da aiye lohùn; li Oluwa wi.22Ilẹ yio si dá ọkà, ati ọti-waini, ati ororo, li ohùn; nwọn o si dá Jesreeli li ohùn.23Emi o si gbìn i fun ara mi lori ilẹ, emi o si ṣãnu fun ẹniti kò ti ri ãnu gbà; emi o si wi fun awọn ti kì iṣe enia mi pe, Iwọ li enia mi; on o si wipe, Iwọ li Ọlọrun mi.Yoruba Bible No Data Yoruba Bible Hosea 2 00:00:00 00:00:00 0.5x 2.0x https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/hosea/002.mp3 14 2