× Language Yuroopu Russian Belarusian Ukrainian Polish Serbian Bulgarian Slovakian Czech Romanian Moldovian Azerbaijan Armenian Georgia Albanian Avar Bashkir Tatar Chechen Slovenian Croatian Estonian Latvian Lithuanian Hungarian Finnish Norwegian Swedish Icelandic Greek Makedonia German Bavarian Dutch Danish Welsh Gaelic .Dè Irish French Basque Catalan Italian Galacian Romani Bosnian Ariwa Amerika English Ila gusu Amerika Spanish Portuguese Guarani Quechuan Aymara Central America Jamaican Nahuatl Kiche Qeqchi Haitian Ila-oorun Asia Chinese Japanese Korean Mongolia Uyguru Hmong Guusu ila oorun Esia Malaysian Burmese Hakha Chin Nepali Cebuano Tagalog Cambodian Thai Indonesian Vietnamese Javanese Lao Iban IuMien Kachin Lahu Aceh Balinese Bugis Pampanga Sasak Shan Waray Guusu Asia Hindi Оdia Awadhi Mizo Kannada Malayalam Marathi Gujarati Tamil Telugu Punjabi Kurukh Ara Assamese Maithili Bengali Urdu Sinhala Dogri Haryanvi Meitei Konkani Santali Sindhi Koya Thado Sanskrit Devanagari Adilabad Gondi Ahirani Balochi Bundeli Chhattisgarhi Garhwali Kangri Kumaoni Mewari Munda Sadri Seraiki Shekhawati Sylheti Aringbungbun Esia Kyrgyz Usibek Tajik Turkmen Kazakhstan Karakalpak Arin Ila-Oorun Turkish Hebrew Arabic Persian Kurdish Pasto Coptic Afirika Afrikaans Xhosa Zulu Ndebele Sotho Amharic Wolaytta Nigerian Mossi Ika Dinka Kabyle Ewe Swahili Morocco Somalian Shona Madagascar Igbo Lingala Baoule Siswati Tsonga Tswana Gambian Yoruba Kamba Kinyarwanda Hausa Chewa Luo Makua Dyula Fulfulde Kalenjin Kikuyu Kikwango Kirundi Krio Nigerian Pidgin Oromo Tshiluba Tshivenda Twi Umbundu Lugbara Luguru Pular Gussi Maasai Turkana Moba Nuer Shilluk Tamasheq Makonde Bemba Fon Hadiyya Ibibio Kimbundu Kimiiru Lango Liberian Kreyol Lomwe Mende Morisyen Ndau Nyankole Sena Sidamo Soga Songe Sukuma Tarifit Teso Tiv Zande Orile-ede Australia New Zealand Papua New Guinea Awọn Ede Atijọ Aramaic Latin Esperanto 1 1 1 YCE 20142010YCE1 1 1 Habakuku GẹnẹsisiEksoduLefitikuNumeriDeuteronomiJoṣuaOnidajọRutu1 Samuẹli2 Samuẹli1 Ọba2 Ọba1 Kronika2 KronikaEsraNehemiahEsteriJobuSaamuÒweOniwaasuOrin SolomoniIsaiahJeremiahẸkun JeremiahEsekiẹliDaniẹliHoseaJoẹliAmosiỌbadiahJonaMikaNahumuHabakukuSefaniahHagaiSekariahMalaki--- --- ---MatiuMarkuLukuJohanuÌṣe àwọn AposteliRomu1 Kọrinti2 KọrintiGalatiaEfesuFilipiKolose1 Tẹsalonika2 Tẹsalonika1 Timotiu2 TimotiuTituFilemoniHeberuJakọbu1 Peteru2 Peteru1 Johanu2 Johanu3 JohanuJudaÌfihàn1 1 1 1 1231 1 1 : 1 12345678910111213141516171 1 1 Yoruba Bible Habakuku 1 Fipamọ Awọn akọsilẹ 1Ọ̀rọ-ìmọ ti Habakuku wolii rí.2Oluwa, emi o ti ke pẹ to, ti iwọ kì yio fi gbọ́! ti emi o kigbe si ọ, niti ìwa-ipa, ti iwọ kì yio si gbalà!3Ẽṣe ti o mu mi ri aiṣedede, ti o si jẹ ki nma wò ìwa-ìka? nitori ikógun ati ìwa-ipá wà niwaju mi: awọn ti si nrú ijà ati ãwọ̀ soke mbẹ.4Nitorina li ofin ṣe di ẹ̀rọ, ti idajọ kò si jade lọ li ẹtọ́; nitoriti ẹni buburu yí olododo ka; nitorina ni idajọ ẹbi ṣe njade.5Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin.6Nitoripe, wò o, emi gbe awọn ara Kaldea dide, orilẹ-ède ti o korò, ti o si yára, ti yio rìn ibú ilẹ na ja, lati ni ibùgbe wọnni, ti kì iṣe ti wọn.7Nwọn ni ẹ̀ru, nwọn si fò ni laiyà: idajọ wọn, ati ọlanla wọn, yio ma ti inu wọn jade.8Ẹṣin wọn pẹlu yara jù ẹkùn lọ, nwọn si muná jù ikõkò aṣãlẹ lọ: ẹlẹṣin wọn yio si tàn ara wọn ka, ẹlẹṣin wọn yio si ti ọ̀na jijìn rére wá; nwọn o si fò bi idì ti nyára lati jẹun.9Gbogbo wọn o si wá fun ìwa-ipá; iwò oju wọn o si wà siwaju, nwọn o si kó igbèkun jọ bi yanrìn.10Nwọn o si ma fi awọn ọba ṣẹsín, awọn ọmọ alade yio si di ẹni-ẹ̀gan fun wọn: gbogbo ibi agbara ni nwọn o si fi rẹrin; nitoripe nwọn o ko erupẹ̀ jọ, nwọn o si gbà a.11Nigbana ni inu rẹ̀ yio yipadà, yio si rekọja, yio si ṣẹ̀, ni kikà agbara rẹ̀ yi si iṣẹ òriṣa rẹ̀.12Lati aiyeraiye ki iwọ ti wà? Oluwa Ọlọrun mi, Ẹni Mimọ́ mi? awa kì yio kú. Oluwa, iwọ ti yàn wọn fun idajọ; Ọlọrun alagbara, iwọ ti fi ẹsẹ̀ wọn mulẹ fun ibawi.13Oju rẹ mọ́ jù ẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò ìwa-ìka: nitori kini iwọ ha ṣe nwò awọn ti nhùwa arekerekè, ti o si pa ẹnu rẹ mọ, nigbati ẹni-buburu jẹ ẹniti iṣe olododo jù u run?14Ti iwọ si nṣe enia bi ẹja okun, bi ohun ti nrakò, ti kò ni alakoso lori wọn?15Iwọ ni àwọn lati fi gbé gbogbo wọn, nwọn nfi àwọn mu wọn, nwọn si nfi awò wọn kó wọn: nitorina ni nwọn ṣe nyọ̀, ti inu wọn si ndùn.16Nitorina, nwọn nrubọ si àwọn wọn, nwọn si nsùn turari fun awò wọn; nitori nipa wọn ni ipin wọn ṣe li ọrá, ti onjẹ wọn si fi di pupọ̀.17Nitorina, nwọn o ha ma dà àwọn wọn, nwọn kì yio ha dẹkun lati ma fọ́ orilẹ-ède gbogbo?Yoruba Bible No Data Yoruba Bible Habakuku 1 00:00:00 00:00:00 0.5x 2.0x https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/habakkuk/001.mp3 3 1