× Language Yuroopu Russian Belarusian Ukrainian Polish Serbian Bulgarian Slovakian Czech Romanian Moldovian Azerbaijan Armenian Georgia Albanian Avar Bashkir Tatar Chechen Slovenian Croatian Estonian Latvian Lithuanian Hungarian Finnish Norwegian Swedish Icelandic Greek Makedonia German Bavarian Dutch Danish Welsh Gaelic .Dè Irish French Basque Catalan Italian Galacian Romani Bosnian Ariwa Amerika English Ila gusu Amerika Spanish Portuguese Guarani Quechuan Aymara Central America Jamaican Nahuatl Kiche Qeqchi Haitian Ila-oorun Asia Chinese Japanese Korean Mongolia Uyguru Hmong Guusu ila oorun Esia Malaysian Burmese Hakha Chin Nepali Cebuano Tagalog Cambodian Thai Indonesian Vietnamese Javanese Lao Iban IuMien Kachin Lahu Aceh Balinese Bugis Pampanga Sasak Shan Waray Guusu Asia Hindi Оdia Awadhi Mizo Kannada Malayalam Marathi Gujarati Tamil Telugu Punjabi Kurukh Ara Assamese Maithili Bengali Urdu Sinhala Dogri Haryanvi Meitei Konkani Santali Sindhi Koya Thado Sanskrit Devanagari Adilabad Gondi Ahirani Balochi Bundeli Chhattisgarhi Garhwali Kangri Kumaoni Mewari Munda Sadri Seraiki Shekhawati Sylheti Aringbungbun Esia Kyrgyz Usibek Tajik Turkmen Kazakhstan Karakalpak Arin Ila-Oorun Turkish Hebrew Arabic Persian Kurdish Pasto Coptic Afirika Afrikaans Xhosa Zulu Ndebele Sotho Amharic Wolaytta Nigerian Mossi Ika Dinka Kabyle Ewe Swahili Morocco Somalian Shona Madagascar Igbo Lingala Baoule Siswati Tsonga Tswana Gambian Yoruba Kamba Kinyarwanda Hausa Chewa Luo Makua Dyula Fulfulde Kalenjin Kikuyu Kikwango Kirundi Krio Nigerian Pidgin Oromo Tshiluba Tshivenda Twi Umbundu Lugbara Luguru Pular Gussi Maasai Turkana Moba Nuer Shilluk Tamasheq Makonde Bemba Fon Hadiyya Ibibio Kimbundu Kimiiru Lango Liberian Kreyol Lomwe Mende Morisyen Ndau Nyankole Sena Sidamo Soga Songe Sukuma Tarifit Teso Tiv Zande Orile-ede Australia New Zealand Papua New Guinea Awọn Ede Atijọ Aramaic Latin Esperanto 1 1 1 YCE 20142010YCE1 1 1 2 Kọrinti GẹnẹsisiEksoduLefitikuNumeriDeuteronomiJoṣuaOnidajọRutu1 Samuẹli2 Samuẹli1 Ọba2 Ọba1 Kronika2 KronikaEsraNehemiahEsteriJobuSaamuÒweOniwaasuOrin SolomoniIsaiahJeremiahẸkun JeremiahEsekiẹliDaniẹliHoseaJoẹliAmosiỌbadiahJonaMikaNahumuHabakukuSefaniahHagaiSekariahMalaki--- --- ---MatiuMarkuLukuJohanuÌṣe àwọn AposteliRomu1 Kọrinti2 KọrintiGalatiaEfesuFilipiKolose1 Tẹsalonika2 Tẹsalonika1 Timotiu2 TimotiuTituFilemoniHeberuJakọbu1 Peteru2 Peteru1 Johanu2 Johanu3 JohanuJudaÌfihàn1 1 1 1 123456789101112131 1 1 : 1 1234567891011121314151617181920212223241 1 1 Yoruba Bible 2 Kọrinti 1 Fipamọ Awọn akọsilẹ 1PAULU Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa, si ijọ Ọlọrun ti o wà ni Korinti, pẹlu, gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà ni gbogbo Akaia:2Õre-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.3Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo;4Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu.5Nitoripe bi ìya Kristi ti di pipọ ninu wa, gẹgẹ bẹ̃ni itunu wa di pipọ pẹlu nipa Kristi.6Ṣugbọn bi a ba si npọ́n wa loju ni, o jasi bi itunu ati igbala nyin, ti nṣiṣẹ ni ifàiyarán awọn iya kannã ti awa pẹlu njẹ: tabi bi a ba ntù wa ninu, o jasi fun itunu ati igbala nyin.7Ati ireti wa nipa tiyin duro ṣinṣin, awa si mọ̀ pe, bi ẹnyin ti jẹ alabapin ninu ìya, bẹ̃li ẹnyin jẹ ninu itunu na pẹlu.8Ará, awa kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li aimọ̀ nipa wahalà wa, ti o dé bá wa ni Asia, niti pe a pọ́n wa loju gidigidi rekọja agbara wa, tobẹ̃ ti ireti kò tilẹ si fun ẹmi wa mọ́:9Ṣugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹle ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti njí okú dide:10Ẹniti o ti gbà wa kuro ninu ikú ti o tobi tobẹ̃, ti o si ngbà wa: ẹniti awa gbẹkẹ wa le pe yio si mã gbà wa sibẹsibẹ;11Ẹnyin pẹlu nfi adura nyin ṣe iranlọwọ fun wa, pe nitori ẹ̀bun ti a fifun wa lati ọwọ ọ̀pọlọpọ enia, ki ọ̀pọlọpọ ki o le mã dupẹ nitori wa.12Nitori eyi ni iṣogo wa, ẹ̀rí-ọkàn wa, pe, ni iwa-mimọ́ ati ododo Ọlọrun, kì iṣe nipa ọgbọ́n ara, bikoṣe nipa ore-ọfẹ Ọlọrun, li awa nhuwa li aiye, ati si nyin li ọ̀pọlọpọ.13Nitoripe awa kò kọwe ohun miran si nyin jù eyi ti ẹnyin kà lọ, tabi ti ẹnyin ti gbà pẹlu: mo si gbẹkẹle pe ẹnyin ó gba a titi de opin;14Gẹgẹ bi ẹnyin si ti jẹwọ wa pẹlu li apakan pe, awa ni iṣogo nyin, gẹgẹ bi ẹnyin pẹlu ti jẹ iṣogo wa li ọjọ Jesu Oluwa.15Ati ninu igbẹkẹle yi ni mo ti ngbèro ati tọ̀ nyin wá niṣãjú, ki ẹnyin ki o le ni ayọ nigbakeji;16Ati lati kọja lọdọ nyin lọ si Makedonia, ati lati tún wá sọdọ nyin lati Makedonia, ati lati mu mi lati ọdọ nyin lọ si Judea.17Nitorina nigbati emi ngbèro bẹ̃, emi ha ṣiyemeji bi? tabi ohun wọnni ti mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹgẹ bi ti ara bi, pe ki o jẹ bẹ̃ni bẹ̃ni, ati bẹ̃kọ, bẹ̃kọ lọdọ mi?18Ṣugbọn bi Ọlọrun ti jẹ olõtọ, ọ̀rọ wa fun nyin kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ.19Nitoripe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, ẹniti a ti wasu rẹ̀ larin nyin nipasẹ wa, ani nipasẹ emi ati Silfanu ati Timotiu, kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ, ṣugbọn ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni.20Nitoripe bi o ti wu ki ileri Ọlọrun pọ̀ to, ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni: ati ninu rẹ̀ pẹlu ni Amin, si ogo Ọlọrun nipasẹ wa.21Njẹ nisisiyi, ẹniti o fi ẹsẹ wa mulẹ pẹlu nyin ninu Kristi, ti o si fi àmi oróro yàn wa, ni Ọlọrun;22Ẹniti o si ti fi èdidi di wa pẹlu, ti o si ti fi akọso eso Ẹmí si wa li ọkàn.23Mo si pè Ọlọrun ṣe ẹlẹri li ọkàn mi pe, nitori lati dá nyin si li emi kò ṣe ti wá si Korinti.24Kì iṣe nitoriti awa tẹ́ gàbá lori igbagbọ́ nyin, ṣugbọn awa jẹ́ oluranlọwọ ayọ̀ nyin: nitori ẹnyin duro nipa igbagbọ́.Yoruba Bible No Data Yoruba Bible 2 Kọrinti 1 00:00:00 00:00:00 0.5x 2.0x https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/2corinthians/001.mp3 13 1