Bible in one year Karun 232 Samuẹli 17:1-291. Lẹ́yìn náà, Ahitofeli wí fún Absalomu pé, “Jẹ́ kí n ṣa ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ọmọ ogun, kí n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa Dafidi lọ lálẹ́ òní.2. N óo kọlù ú nígbà tí àárẹ̀ bá mú un; tí ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì; ẹ̀rù yóo bà á, gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ yóo sì sá lọ. Ọba nìkan ṣoṣo ni n óo pa.3. N óo sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí iyawo tí ó lọ bá ọkọ rẹ̀ nílé. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni o fẹ́ pa, àwọn eniyan yòókù yóo sì wà ní alaafia.”4. Ìmọ̀ràn náà dára lójú Absalomu ati gbogbo àgbààgbà Israẹli.5. Ṣugbọn Absalomu dáhùn pé, “Ẹ pe Huṣai wá, kí á gbọ́ ohun tí òun náà yóo sọ.”6. Nígbà tí Huṣai dé, Absalomu wí fún un pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún wa nìyí, ṣé kí á tẹ̀lé e? Bí kò bá yẹ kí á tẹ̀lé e, sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa.”7. Huṣai dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Kabiyesi ní àkókò yìí, kò dára.8. Ṣebí o mọ̀ pé, akikanju jagunjagun ni baba rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀? Ara kan wọ́n báyìí, wọn yóo sì rorò ju abo ẹkùn beari tí ọdẹ jí lọ́mọ kó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni jagunjagun tí ó ní ọpọlọpọ ìrírí ni baba rẹ, kò sì ní sùn lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní alẹ́ yìí.9. Bóyá bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ninu ihò ilẹ̀ níbìkan ni ó wà tabi ibòmíràn. Bí Dafidi bá kọlu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì pa díẹ̀ ninu wọn, àwọn tí wọ́n bá gbọ́ yóo wí pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn eniyan Absalomu.10. Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.11. Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà.12. A óo kọlu Dafidi níbikíbi tí a bá ti bá a, a óo bò wọ́n bí ìgbà tí ìrì bá sẹ̀ sórí ilẹ̀; ẹnikẹ́ni kò sì ní yè ninu òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.13. Bí ó bá sá wọ inú ìlú kan, àwọn ọmọ Israẹli yóo fi okùn fa ìlú náà lulẹ̀ sinu àfonífojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ẹyọ òkúta kan ṣoṣo kò ní ṣẹ́kù sórí òkè náà.”14. Absalomu ati gbogbo Israẹli dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn ti Huṣai dára ju ti Ahitofeli lọ,” nítorí pé OLUWA ti pinnu láti yí ìmọ̀ràn rere tí Ahitofeli mú wá pada, kí ibi lè bá Absalomu.15. Huṣai bá lọ sọ fún Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji, irú ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli, ati èyí tí òun fún wọn.16. Huṣai tún fi kún un pé, kí wọ́n ranṣẹ kíákíá lọ sọ fún Dafidi pé, kò gbọdọ̀ sùn níbi tí wọ́n ti ń ré odò Jọdani kọjá ninu aṣálẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Ó gbọdọ̀ kọjá sí òdìkejì odò lẹsẹkẹsẹ kí ọwọ́ má baà tẹ̀ ẹ́ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n.17. Jonatani ati Ahimaasi dúró sí ibi orísun Enrogeli, ní ìgbèríko ati máa lọ sí Jerusalẹmu, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fojú kàn wọ́n, pé wọ́n wọ ìlú rárá. Iranṣẹbinrin kan ni ó máa ń lọ sọ ohun tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ fún wọn, àwọn náà á lọ sọ fún Dafidi.18. Ṣugbọn ọmọkunrin kan rí wọn, ó sì sọ fún Absalomu. Jonatani ati Ahimaasi bá sáré lọ fi ara pamọ́ ní ilé ọkunrin kan ní Bahurimu. Ọkunrin yìí ní kànga kan ní àgbàlá ilé rẹ̀. Àwọn mejeeji bá kó sinu kànga náà.19. Aya ọkunrin náà fi nǹkan dé e lórí, ó sì da ọkà bàbà lé e kí ẹnikẹ́ni má baà fura sí i.20. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Absalomu dé ọ̀dọ̀ obinrin náà, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Ahimaasi ati Jonatani wà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti kọjá sí òdìkejì odò.” Àwọn ọkunrin náà wá wọn títí, ṣugbọn wọn kò rí wọn. Wọ́n bá pada lọ sí Jerusalẹmu.21. Nígbà tí àwọn ọkunrin náà lọ tán, Ahimaasi ati Jonatani jáde ninu kànga, wọ́n sì lọ ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Dafidi. Wọ́n sọ ohun tí Ahitofeli ti gbèrò láti ṣe sí Dafidi. Wọ́n ní kí ó yára, kí ó rékọjá sí òdìkejì odò náà kíá.22. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Nígbà tí ilẹ̀ yóo fi mọ́, gbogbo wọn ti kọjá tán.23. Nígbà tí Ahitofeli rí i pé, Absalomu kò tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí òun fún un, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó pada lọ sí ìlú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti ṣètò ilé rẹ̀, ó pokùnso, ó bá kú; wọ́n sì sin ín sí ibojì ìdílé rẹ̀.24. Nígbà tí Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ré odò Jọdani kọjá tán, Dafidi ti dé ìlú tí wọn ń pè ní Mahanaimu.25. Amasa ni Absalomu fi ṣe olórí ogun rẹ̀, dípò Joabu. Itira ará Iṣimaeli ni baba Amasa. Ìyá rẹ̀ sì ni Abigaili, ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruaya, ìyá Joabu.26. Absalomu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí ilẹ̀ Gileadi.27. Nígbà tí Dafidi dé Mahanaimu, Ṣobi, ọmọ Nahaṣi, wá pàdé rẹ̀, láti ìlú Raba, ní ilẹ̀ Amoni. Makiri, ọmọ Amieli, náà wá, láti Lodebari; ati Basilai, láti Rogelimu, ní ilẹ̀ Gileadi.28. Wọ́n kó ibùsùn lọ́wọ́ wá fún wọn, ati àwo, ìkòkò ati ọkà baali, ọkà tí wọ́n ti lọ̀, ati èyí tí wọ́n ti yan, erèé ati ẹ̀fọ́;29. oyin, omi wàrà, ati wàrà sísè. Wọ́n sì kó aguntan wá pẹlu, láti inú agbo wọn fún Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀, kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ. Nítorí wọ́n rò pé yóo ti rẹ̀ wọ́n, ebi yóo ti máa pa wọ́n, òùngbẹ yóo sì ti máa gbẹ wọ́n, ninu aṣálẹ̀ tí wọ́n wà.2 Samuẹli 18:1-331. Dafidi kó gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó pín wọn ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000), ó fi balogun kọ̀ọ̀kan ṣe olórí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan.2. Lẹ́yìn náà, ó rán wọn jáde ní ìpín mẹta, ó fi Joabu, ati Abiṣai, ọmọ Seruaya, àbúrò Joabu, ati Itai, ará Gati, ṣe ọ̀gágun àgbà ìpín kọ̀ọ̀kan. Ó ní òun pàápàá yóo bá wọn lọ.3. Ṣugbọn wọ́n dá a lóhùn pé, “O kò ní bá wa lọ, nítorí pé bí a bá sá lójú ogun ní tiwa, tabi tí ìdajì ninu wa bá kú, kò jẹ́ ohunkohun fún àwọn ọ̀tá wa. Ṣugbọn ìwọ nìkan ju ẹgbaarun (10,000) wa lọ. Ohun tí ó dára ni pé kí o dúró ní ìlú, kí o sì máa fi nǹkan ranṣẹ sí wa láti fi ràn wá lọ́wọ́.”4. Ọba dáhùn pé, “Ohunkohun tí ẹ bá ní kí n ṣe náà ni n óo ṣe.” Ọba bá dúró ní ẹnu ibodè, bí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ń tò kọjá lọ ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000).5. Ó pàṣẹ fún Joabu, ati Abiṣai, ati Itai, ó ní, “Nítorí tèmi, ẹ má pa Absalomu lára.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì gbọ́ nígbà tí Dafidi ń pa àṣẹ yìí fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀.6. Àwọn ọmọ ogun náà bá jáde lọ sinu pápá láti bá àwọn ọmọ ogun Israẹli jà, ní aṣálẹ̀ Efuraimu.7. Àwọn ọmọ ogun Dafidi ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Israẹli. Wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní ọjọ́ náà. Àwọn tí wọ́n kú lára wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000).8. Ogun náà tàn káàkiri gbogbo agbègbè; àwọn tí wọ́n sì sọnù sinu igbó pọ̀ ju àwọn tí wọ́n fi idà pa lójú ogun lọ.9. Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀.10. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku.11. Joabu dá a lóhùn pé, “Nígbà tí o rí i, kí ló dé tí o kò pa á níbẹ̀ lẹsẹkẹsẹ? Inú mi ìbá dùn láti fún ọ ní owó fadaka mẹ́wàá ati ìgbànú akikanju ninu ogun jíjà.”12. Ṣugbọn ọmọ ogun náà dáhùn pé, “Ò báà tilẹ̀ fún mi ní ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka, n kò ní ṣíwọ́ sókè pa ọmọ ọba. Gbogbo wa ni a gbọ́, nígbà tí ọba pàṣẹ fún ìwọ ati Abiṣai ati Itai pé, nítorí ti òun ọba, kí ẹ má pa Absalomu lára.13. Tí mo bá ṣe àìgbọràn sí òfin ọba, tí mo sì pa Absalomu, ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́, bí ọba bá sì gbọ́, ìwọ gan-an kò ní gbà mí sílẹ̀.”14. Joabu dáhùn pé, “N kò ní máa fi àkókò mi ṣòfò, kí n sọ pé mò ń bá ọ sọ̀rọ̀.” Joabu bá mú ọ̀kọ̀ mẹta, ó sọ wọ́n lu Absalomu ní igbá àyà lórí igi oaku tí ó há sí.15. Mẹ́wàá ninu àwọn ọdọmọkunrin tí wọn ń ru ihamọra Joabu bá yí Absalomu po, wọ́n sì ṣá a pa.16. Lẹ́yìn náà, Joabu fọn fèrè ogun, kí wọ́n dáwọ́ ogun jíjà dúró. Àwọn ọmọ ogun Dafidi bá pada lẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Israẹli.17. Wọ́n gbé òkú Absalomu jù sinu ihò jíjìn kan ninu igbó, wọ́n sì kó ọpọlọpọ òkúta jọ sórí òkú rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ.18. Nígbà ayé Absalomu, ó ṣe ọ̀wọ̀n ìrántí kan fún ara rẹ̀ ní àfonífojì ọba, nítorí kò ní ọmọkunrin kankan tí ó le gbé orúkọ rẹ̀ ró. Nítorí náà ni ó ṣe sọ ọ̀wọ̀n náà ní orúkọ ara rẹ̀; ọ̀wọ̀n Absalomu ni wọ́n ń pe ọ̀wọ̀n náà, títí di òní olónìí.19. Ahimaasi, ọmọ Sadoku bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí n sáré tọ ọba lọ, kí n sì fún un ní ìròyìn ayọ̀ náà, pé OLUWA ti gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”20. Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn pé, “Rárá o, kì í ṣe ìwọ ni o óo mú ìròyìn náà lọ lónìí, bí ó bá di ọjọ́ mìíràn, o lè mú ìròyìn ayọ̀ lọ. Kì í ṣe òní, nítorí pé ọmọ ọba ni ó kú.”21. Joabu bá sọ fún ọ̀kan ninu àwọn ará Kuṣi pé, “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ará Kuṣi náà bá tẹríba fún Joabu, ó sì sáré lọ.22. Ṣugbọn Ahimaasi ṣá tẹnu mọ́ ọn pé, “N kò kọ ohunkohun tí ó lè ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sáré tẹ̀lé ará Kuṣi náà lọ.” Joabu bi í pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ, ọmọ mi? Kò sí èrè kankan fún ọ níbẹ̀.”23. Ahimaasi dáhùn pé, “Mo ṣá fẹ́ lọ ni, ohun yòówù tí ó lè ṣẹlẹ̀.” Joabu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ bí o bá fẹ́, máa lọ.” Ahimaasi bá sáré gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì ṣáájú ará Kuṣi náà.24. Dafidi wà ní àlàfo tí ó wà ní ààrin ẹnu ọ̀nà tinú ati ti òde, ní ẹnu ibodè ìlú. Ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ bodè gun orí odi lọ, ó dúró lé orí òrùlé ẹnubodè. Bí ó ṣe gbé ojú sókè, ó rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń sáré bọ̀.25. Ó pe ọba nísàlẹ̀, ó sì sọ fún un, ọba bá dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó ń mú bọ̀.” Ẹni tí ń sáré bọ̀ náà túbọ̀ ń súnmọ́ tòsí.26. Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.” Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.”27. Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.” Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.”28. Ahimaasi bá kígbe sókè pé, “Alaafia ni!” Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú ọba, ó sì wí fún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ tí ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba, oluwa mi.”29. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?” Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.”30. Ọba bá ní kí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ kan ná, ó bá dúró.31. Lẹ́yìn náà, ará Kuṣi náà dé, ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún oluwa mi, ọba! Nítorí pé, OLUWA ti fún ọ ní ìṣẹ́gun lónìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́.”32. Ọba bi í pé, “Ṣé alaafia ni Absalomu, ọmọ mi wà?” Ará Kuṣi náà dáhùn pé, “Kí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Absalomu ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ, ati gbogbo àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọ.”33. Ìbànújẹ́ ńlá dé bá ọba, ó bá gun òkè lọ sinu yàrá tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà ibodè, ó sì sọkún. Bí ó ti ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ké pé, “Ha! Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Ọmọ mi! Kì bá ṣe pé ó ṣeéṣe ni, kí n kú dípò rẹ, Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi!”Saamu 66:16-2016. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi.17. Mo ké pè é, mo sì kọrin yìn ín.18. Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi, OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi.19. Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́; ó sì ti dáhùn adura mi.20. Ìyìn ni fún Ọlọrun, nítorí pé kò kọ adura mi; kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi.Òwe 16:31-3231. Adé ògo ni ewú orí, nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i.32. Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ, ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ.Johanu 7:28-5328. Ni Jesu bá kígbe sókè bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili. Ó ní, “Òtítọ́ ni pe ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, tí ẹ̀yin kò mọ̀.29. Èmi mọ̀ ọ́n, nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó sì rán mi níṣẹ́.”30. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fi ọwọ́ kàn án nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.31. Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan gbà á gbọ́, wọ́n ń sọ pé, “Bí Mesaya náà bá dé, ǹjẹ́ yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu ju èyí tí ọkunrin yìí ń ṣe lọ?”32. Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn eniyan ń sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ báyìí láàrin ara wọn nípa Jesu. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá rán àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili pé kí wọ́n lọ mú Jesu wá.33. Jesu bá dáhùn pé, “Àkókò díẹ̀ ni ó kù tí n óo lò pẹlu yín, lẹ́yìn náà n óo lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.34. Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, ibi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀.”35. Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Níbo ni ọkunrin yìí yóo lọ tí àwa kò fi ní rí i? Àbí ó ha fẹ́ lọ sí ààrin àwọn ará wa tí ó fọ́nká sí ààrin àwọn Giriki ni?36. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí tí ó sọ pé, ‘Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, níbi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀?’ ”37. Nígbà tí ó di ọjọ́ tíí àjọ̀dún yóo parí, tíí ṣe ọjọ́ tí ó ṣe pataki jùlọ, Jesu dìde dúró, ó kígbe pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó mu omi.38. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóo ti máa sun jáde, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.”39. Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo.40. Ninu àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni wolii tí à ń retí nítòótọ́.”41. Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Òun ni Mesaya.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Báwo ni Mesaya ti ṣe lè wá láti Galili?42. Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”43. Ni ìyapa bá bẹ́ sáàrin àwọn eniyan nítorí rẹ̀.44. Àwọn kan ninu wọn fẹ́ mú un, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn án.45. Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili tí wọ́n rán lọ mú Jesu pada dé ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi mú un wá?”46. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọ̀hún bá dáhùn pé, “Ẹnikẹ́ni kò sọ̀rọ̀ bí ọkunrin yìí rí!”47. Àwọn Farisi bá bi wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin náà ti di ara àwọn tí ó ń tàn jẹ?48. Ṣé kò ṣá sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn aláṣẹ ati àwọn Farisi tí ó gbà á gbọ́?49. A ti fi àwọn eniyan wọnyi tí kò mọ Òfin Mose gégùn-ún!”50. Ọ̀kan ninu àwọn Farisi ọ̀hún ni Nikodemu, ẹni tí ó lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan. Ó bi wọ́n léèrè pé,51. “Ǹjẹ́ òfin wa dá eniyan lẹ́bi láìjẹ́ pé a kọ́ gbọ́ ti ẹnu rẹ̀, kí á mọ ohun tí ó ṣe?”52. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àbí ará Galili ni ìwọ náà? Lọ wádìí kí o rí i pé wolii kankan kò lè ti Galili wá!” Yoruba Bible (BM) 2010 Bible Society of Nigeria © 1900/2010